Published 4 years ago in Other

DÌDE OLUWA (Princess Stella Olukayode).mp3

  • 39
  • 1
  • 0
  • 3
  • 0
  • 0

A Single Track by Princess Stella Olukayode

Released on 26th of June 2021

Titled : Dide Oluwa

Lyrics

DIDE OLUWA

Chorus :
Dide Oluwa tete wa soro saye mi o/2*/
Iya ti mo je Lagiju yii ti to ge oo,
Dide Oluwa tete wa soro saye mi o kiakia.

Sollo 1 : 1Samuel 16
Laarin omo Jesse Loluwa ti fa dafidi yoo,
Aguntan lon so nigba to Lorun ran samueli wa o
Jesse mu omo re mejeeje koja Ni waju samueli sugbo samueli wi fun pe oluwa ko yan awon won yii,
Samueli bi Jesse leere pe, se gbogbo omo re lowa Ni bi,
Jesse daloun o wi fun wipe abikeyin won lo ku oo
Saawo nibi to wa yen se lon so Aguntan oo, samueli ranse pe dafidi won ko si joko titi to fi de, oluwa oya dafidi Soto Laarin awon arakunrin re oo
Lagiju ti mo wayii Oluwa mu mi Jade oo
Kori mi di ori apesin, ki gbogbo aye parapo bami yin oo
Ah ah, Ah ah, Baba Dide oo...

Sollo 2 : Mark 10
Batimeu omo Timeu joko leba ona o n sagbe
Nigba to gbo pe Jesu ti Nasareti lon koja
Obere sini n kigbe lohun rara wipe,
Jesu Omo Dafidi Saanu Mi,
Jesu dese duro fun, obileere kilofe
Oni RABBONI, Ki emi ki o le riran
Jesu Ni ko maa lo, igbagbo re mu Lara da
Loju kan naa, o riran osi to Jesu leyin oo
Emi na Tujuka, Mo Dide, Mo Satoowa, Mo n kigbe wipe Jesu Omo Dafidi Saanu Mi
Ma Jen wa bakanaa mo, wa mu leri se o, kowore Yi owo pada, mu mi koro Lagiju airi oloore
Ah ah, Ah ah, Ma lo lai semiloore oo...

Call : Saanu Mi, Gbemi soke, Yori mi soke faraye rii
Resp : Dide Oluwa Tete wa sòrò saye mi oo kia kia
Call : Owo Oluwa koyi aye mi pada, So aye mi ji oo sinu Ogo Tuntun
Call : Bi batimeu omo Timeu ti kigbe loun rara, Mo n kigbe Saanu Mi
Call : Gege bi o ti dese duro gbo ti batimeu, dese duro gbo temi oo
Call : Saanu Mi ni gbogbo ona, Kaye ma ba bere pe Olorun mi da
Call : Ki oloore wa mi ri, Ki Ìgba mi ma se koja mi
Call : Aanu ni mo nilo ni korita ko si aanu mo oo
Call : Iranlowo re ni mo ni lo ni korita ko si Iranlowo mo oo
Call : Ilekun Aseyori ti ota ti ti, ko bere si ni ma si Loruko Jesu
Call : Saanu Mi lona iye yii ma Jen subu deru Ogo mi danu
Call : So igba mi dotun, Kemi ri iyanu re laye mi
Call : Ala ati Iran ojo iwaju mi yii, Ko se mo mi Lara mu ileri se
Call : Majen fekun sin o mo Oto Akoko so agbegbe mi di nla oo
Call : Tori mo ni o lolugbeja Ajamajebi o, Gbemi Ni ja
Call : Tori mo ni o lolugbeja Ajamajebi o, Ja fun mi
Call : Wa soro o, Wa soro o, Wa soro o, si ise iranse mi oo, Sinu ipe mi oo, igbe dide.
???

:
/ :

Queue

Clear